Ìkòyí èshó, Ọmọ agbọn iyùn, Ogun ajaaiweeyin lọ meso wù mí, Ogun ojoojumo lo mú kilee wọn sú mí lọ, èshó kí gba ọfà lẹ́yìn, Gbangba iwájú ni wọn fí gbaọta, Ọmọ oni Ìkòyí akoko, Èyin lọmọ àgbà tín yàrun ọ̀tẹ̀, Ọmọ ogun lérè jọjà lọ, Ìkòyí ọmọ Aporogunjo, Ìkòyí gbéra ń lé ó dìde ogun yá, Ọjọ́ Kínní tó nìkòyí kú, Ṣùgbọ́n mo kúrò lọmọ agbekórùn lọ oko, Wọn gbélé wọn bo onìkòyí Àgbède gbede onìkòyí lọ sùn ibè, Àtàrí onìkòyí Kò sún ibè, Àwọn lọmọ aṣíjú àpò piri dàgbà ọfà sọ fún,pofún yóò yọ dàgbà ọfà sile, Ọmọ aku fepo tele koto, Ọmọ igunnugun balẹ̀ wọn a jori akalamagbo balẹ̀ wọn a jẹdọ.
Ìkòyí èshó,
Ọmọ agbọn iyùn,
Ogun ajaaiweeyin lọ meso wù mí,
Ogun ojoojumo lo mú kilee wọn sú mí lọ,
èshó kí gba ọfà lẹ́yìn,
Gbangba iwájú ni wọn fí gbaọta,
Ọmọ oni Ìkòyí akoko,
Èyin lọmọ àgbà tín yàrun ọ̀tẹ̀,
Ọmọ ogun lérè jọjà lọ,
Ìkòyí ọmọ Aporogunjo,
Ìkòyí gbéra ń lé ó dìde ogun yá,
Ọjọ́ Kínní tó nìkòyí kú,
Ṣùgbọ́n mo kúrò lọmọ agbekórùn lọ oko,
Wọn gbélé wọn bo onìkòyí
Àgbède gbede onìkòyí lọ sùn ibè,
Àtàrí onìkòyí Kò sún ibè,
Àwọn lọmọ aṣíjú àpò piri dàgbà ọfà sọ fún,pofún yóò yọ dàgbà ọfà sile,
Ọmọ aku fepo tele koto,
Ọmọ igunnugun balẹ̀ wọn a jori akalamagbo balẹ̀ wọn a jẹdọ.